explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa Abdullahi Bn Jud’aan, o si wa ninu awọn aṣiwaju Kuraiṣi ṣíwájú Isilaamu, Ninu awọn iṣẹ daadaa rẹ ni pé: O maa n da awọn ẹbi pọ, o si maa n ṣe daadaa si wọn, o si maa n fun alaini ni oúnjẹ, ati eyi ti o yàtọ̀ si wọn ninu awọn iwa ọlọla ti Isilaamu ṣe wa lojukokoro lori ṣíṣe wọn, ati pe awọn iṣẹ yii ko lee ṣe e ni anfaani ni ọjọ igbedide rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ fun okunfa ṣíṣe aigbagbọ rẹ ninu Ọlọhun, ati pe ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, forí awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Alaye ọla ti o n bẹ fun nini igbagbọ, ati pe o jẹ majẹmu fun gbigba awọn iṣẹ.
  • Alaye apẹrẹ buruku aigbagbọ, ati pe o wa ninu awọn nnkan ti o n ba awọn iṣẹ oloore jẹ.
  • Àwọn alaigbagbọ, awọn iṣẹ wọn ko nii ṣe wọn ni anfaani ni ọjọ igbedide nitori aigbagbọ wọn ninu Ọlọhun ati ọjọ igbedide.
  • Àwọn iṣẹ́ ọmọniyan ni ipo aigbagbọ rẹ, wọn maa kọ wọn fun un ti o ba gba Isilaamu, wọn yoo si san an ni ẹsan lori wọn.