explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju adehun ati majẹmu ti o wa laaarin awọn Musulumi ati laaarin awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn alaigbagbọ ati awọn ṣọbẹ-selu ni irun kiki, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Titobi ipo irun, ati pe oun ni ipinya ti o wa laaarin olugbagbọ ati alaigbagbọ.
  • Fifi awọn idajọ Isilaamu rinlẹ pẹlu nnkan ti o ba han ninu isẹsi awọn eniyan yatọ si eyi ti o pamọ.