explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba gbagbe lati ki eyikeyii irun kan ti a ṣe e ni ọran-anyan titi asiko fi lọ, o jẹ dandan fun un lati tete ki o si yara lọ san an ni kete ti o ba ti ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ ati bibo fun ẹṣẹ gbigbe e ju silẹ afi ki Musulumi naa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, Ọlọhun sọ ninu iwe Rẹ Alapọn-ọnle pé: (Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.) (Ta-Ha: 14), o n túmọ̀ si pe: Ki o si ki irun ti a gbagbe nigba ti o ba ti ranti rẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Alaye pataki irun ati aimaṣe ọlẹ nibi kiki rẹ ati sisan an padà.
  • Lilọ irun lara tayọ asiko rẹ ko lẹtoọ ni ti mọọmọ laini awijare.
  • Jijẹ dandan sisan irun pada fun ẹni ti o ba gbagbe ti o ba ti ranti ati ẹni ti o sun ti o ba ti ji.
  • Jijẹ dandan sisan awọn irun pada ni yara yara koda ko jẹ awọn asiko ti a ṣe kiki irun ni eewọ nibẹ.