explain-icon

Àlàyé

Wọn darukọ ọkunrin kan lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti o sun titi ti ilẹ fi mọ ti orun fi yọ ti kò si dide kirun ọranyan, ni Anabi ba sọ pe: oun ni arakunrin kan ti èṣù (Satani) ti tọ sí inu eti rẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Kikorira fifi idide kirun lóru silẹ, nitori okunfa èṣù (Satani) ni.
  • Isọra nipa èṣù (Satani) eyi ti n ma joko sí gbogbo oju ona de ọmọniyan lati le dina laarin rẹ ati itẹle àṣẹ Ọlọhun Ọba to gbọngbọn ti O ga.
  • Ibn Hajar sọ pé: gbólóhùn rẹ tó sọ pé: (ko dide lọ kirun) ohun ti wọn gba lero ni iran, o sì lè túmọ sí ohun ti a ti bá sábà, irun òru tabi irun ọranyan ni wọn lè gbà lero.
  • At-Tiibiyy sọ pé: wọn da eti yan láti darukọ, bo tiẹ jẹ pe oju ni o ni ìbátan pẹlu orun, nitori ati tọkasi wíwọra orun naa, dájúdájú eti igbọrọ ni ààyè itaji, wọn si sa itọ yan; nitoripe ohun ni o rọrùn ju láti ko wọnu awọn iho, òhun sì ni ọ yara ju lati ta pọrọ wọnu isan ara, eyi ti yóò padà jogun oroju sí gbogbo orikerike ara.