Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki irun asunbaa ni Hudaibiya- oun ni oko kan ti o sunmọ Mẹka- lẹyin ti ojo rọ ni alẹ yẹn, Igba ti o salamọ ti o ki irun rẹ tan o doju kọ awọn eniyan, o si bi wọn pe: Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ? Wọn da a lohun pe: Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, O sọ pe: Dajudaju Ọlọhun ṣàlàyé pe awọn eniyan pin si meji nigba ti ojo ba rọ: Ipin kan ti o ni igbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati ipin ti o jẹ alaigbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Ṣugbọn ẹni ti o sọ pe: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ, ti o fi rirọ ojo ti sọ́dọ̀ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-; ìyẹn ni olugbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Aṣẹ̀dá Aṣeyiowuu ninu aye, o si jẹ alaigbagbọ si irawọ. Ṣugbọn ẹni ti o ba sọ pe: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu irawọ bayii bayii; ìyẹn ni alaigbagbọ ninu Ọlọhun, olugbagbọ ninu irawọ, o si jẹ aigbagbọ kekere nigba ti o ṣe afiti rirọ ojo si ara irawọ; ati pe Ọlọhun ko ṣe e ni okunfa ti sharia tabi ti kadara, Ṣugbọn ẹni ti o ba ṣe afiti rirọ ojo ati nnkan ti o yàtọ̀ si i ninu awọn ìṣẹ̀lẹ̀ ori ilẹ̀ si ara lilọ-bibọ àwọn ìràwọ̀ nibi yíyọ wọn ati jijabọ wọn, ti o n ni adisọkan pe oun ni ẹni ti o n ṣe e gangan, o ti jẹ alaigbagbọ ni aigbagbọ ti o tobi.