Mu’aadh ọmọ Jabal- ki Ọlọhun yọnu si i- wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori nǹkan ọ̀gùn rẹ, o wa pe e: Irẹ Mu’aadh? O paara pipe e rẹ lẹẹmẹta; lati fi pataki nnkan ti o fẹ sọ rinlẹ. Ati pe gbogbo ìyẹn ni Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i- n da a lohun pẹlu ọrọ rẹ pé: “LABBAEKA YAA ROSUULALLOOHI WA SAHDAEK”, o n túmọ̀ sí pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun ni idahun kan lẹyin idahun, mo si n tọrọ oriire fun jijẹ ìpè rẹ. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pe ko si ẹnikẹni ti o n jẹrii pe LAA ILAAHA ILLALLOOH, itumọ rẹ ni pe: Ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, lododo lati inu ọkan rẹ lai parọ, ti o ba ku lori iṣesi yii, Ọlọhun maa ṣe ina leewọ fun un. Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i- wa beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe ṣe ki oun sọ ọ fun awọn eniyan ki wọn le yọ ki wọn si dunnú si dáadáa? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa paya pe ki wọn ma baa gbara le e, ti iṣẹ wọn fi maa kere. Mu’aadh ko sọ hadiisi naa fun ẹnikẹni afi ṣiwaju iku rẹ; ni ti ipaya kikosi inu ẹṣẹ fifi imọ pamọ.