explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ohunkóhun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí Mùsùlùmí, bii aisan ati ironu ati ibanujẹ ati ajalu ati ile koko ati ipaya ati ebi- koda ki o jẹ ẹgun ni o gun un ti o wa n ko inira ba a-, ìyẹn maa jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun awọn ẹṣẹ rẹ ati awọn aṣiṣe rẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Alaye ọla ti o n bẹ fun Ọlọhun lori awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ati ikẹ Rẹ pẹlu wọn pẹlu iforijin awọn ẹṣẹ wọn pẹlu eyi ti o kere julọ ninu inira ti o ba ṣẹlẹ̀ si wọn.
  • O tọ fun Musulumi lati maa reti ẹsan nnkan ti o ṣẹlẹ̀ si i lọdọ Ọlọhun, ki o si ṣe suuru lori gbogbo nnkan kekere ati ńlá, ki agbega ninu awọn ipo le jẹ tirẹ ati ipa awọn aburu rẹ.