Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe iran mẹfa ni àwọn iṣẹ, iran mẹ́rin si ni àwọn èèyàn. Àwọn iṣẹ́ mẹfẹẹfa naa ni: Akọkọ: Ẹni tí ó bá ku ti ko da nnkan kan pọ mọ Ọlọhun, alujanna di dandan fun un. Ẹlẹẹkeji: Ẹni tí ó bá kú ti o si da nǹkan pọ mọ Ọlọhun, ina di dandan fún un, yoo si ṣe gbere ninu ẹ. Àwọn mejeeji ni nnkan meji ti wọn maa n sọ nǹkan di dandan. Ẹlẹẹkẹta: Daadaa ti a gbero, ẹni tí ó bá gbero lati ṣe dáadáa pẹ̀lú aniyan òdodo titi ti ọkan rẹ fi maa mọ ọn lara ti Ọlọhun naa si mọ àníyàn yii lati ọdọ rẹ, ki àlámọ̀rí kan waa sẹlẹ si i lẹ́yìn naa, ti ko waa ni ikapa lati ṣe daadaa yii, wọn maa kọ ẹsan ti o pe fun un. Ikẹrin: Aburu ti a ṣe, ẹni ti o ba ṣe aburu kan wọn maa kọ aburu kan fun un. Àwọn mejeeji ni: Iru kan pẹlu iru kan laini adipele. Ikarun-un: Daadaa ti o maa jẹ pẹlu daadaa mẹwaa iru rẹ, oun ni ẹni ti o gbero daadaa ti o si ṣe é; wọn maa kọ daadaa mẹwaa fun un. Ikẹfa: Daadaa ti o maa jẹ pẹlu ẹẹdẹgbẹrin ẹsan, oun ni ẹni ti o ba na owó kan si oju ọna Ọlọhun, wọn maa kọ daadaa yii fun un pẹlu ẹẹdẹgbẹrin daadaa, eleyii wa ninu ọlá Rẹ- ìbùkún ni fun Un ti ọla Rẹ ga- ati ọrẹ Rẹ lori awọn ẹru Rẹ. Ṣugbọn àwọn iran awọn eniyan mẹrẹẹrin ni: Akọkọ: Ẹni ti wọn maa gba laaye ni aye ninu arisiki, wọn maa dẹ ẹ lara nibẹ pẹlu nnkan ti o ba fẹ, sugbọn wọn maa fun pinpin mọ ọn ni ọrun ti ìkángun rẹ si maa jẹ ina, oun ni alaigbagbọ ọlọrọ. Ikeji: Ẹni ti wọn maa fun pinpin mọ ọn ni aye ninu arisiki, sugbọn wọn maa gba a laaye ni ọrun, ti ìkángun rẹ si maa jẹ alujanna, oun ni olugbagbọ alaini. Ikẹta: Ẹni ti wọn maa fun pinpin mọ ọn ni aye ati ọrun, oun ni alaigbagbọ alaini. Ikẹrin: Ẹni ti wọn maa gba a laaye ni aye ati ọrun, oun ni olugbagbọ ọlọrọ.