Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe saara kii din dúkìá ku, bi ko ṣe pe o maa n ti àwọn nǹkan ti o le ba a jẹ́ danu, Ọlọhun si maa n fi oore ńlá rọ́pò fun ẹni tí n ṣe saara, o maa wa jẹ alekun ni kii ṣe adinku. Amojukuro pẹlu ikapa lati gba ẹsan kii le ẹni ti o ba ṣe e kun nǹkan kan ayafi ni agbara. Ẹnikan ko nii tẹrí ba tori ti Ọlọhun, ti kii ṣe ti ibẹru ẹnikẹ́ni, tabi ti ẹ̀tàn, tabi wiwa anfaani kan lọ́dọ̀ rẹ, àyàfi ki ẹsan rẹ o jẹ gíga ati iyì.