Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti fún wa ni iro pe kosi ọjọ kan ti oorun yọ ayaafi ki awọn malaika meji sọkale ti wọn yóò sì máa pe Ọlọhun, ọkan ninu wọn yóò sọ pé: "Ọlọhun bami fi ọpọ rọpo fún ẹni tí n nawo rẹ ni itẹle aṣẹ Ọlọhun, ati fún awọn ẹbi (ọmọ, iyawo, baba, ati iya....) ati igbalejo, ati sí bi awọn iṣẹ àṣegbọrẹ, bami fi èyí to lóore pupọ ju èyí to na lọ rọpo fun un, ki o si ṣe ibukún Rẹ fun". Ẹnikeji awọn malaika náà yóò máa sọ pe: "Ọlọhun bá mi ṣe iparẹ ati ibajẹ sí owo ẹni tí ó kọ̀ lati maa na owo rẹ, bá mi ko iparun ba owo tabi dukia tí ó kọ̀ lati na fún awọn ti o lẹtọọ sí i".