Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun maa ṣẹsa arakunrin kan ninu ijọ rẹ lójú awọn ẹda ni ọjọ igbedide, wọn maa pe e lati ṣe ìṣirò iṣẹ fun un, O si maa fi iwe àkọsílẹ̀ mọkandinlọgọrun-un han an, àwọn naa ni awọn iwe awọn iṣẹ aburu rẹ ti o n ṣe ni aye, ati pe òró iwe àkọsílẹ̀ kọọkan gùn ni ìwọ̀n ibi tí irina ba dé, Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun arakunrin naa pe: Njẹ waa tako nnkankan ninu nnkan ti wọn kọ sinu awọn iwe àkọsílẹ̀ yii? Njẹ awọn Mọlaika mi Olùṣọ́ Olukọwe ṣe abosi rẹ? Arakunrin naa maa sọ pé: Rara Oluwa mi. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Njẹ awijare n bẹ fun ẹ ninu nnkan ti o ti siwaju ninu awọn iṣẹ ni aye? Bóyá o jẹ igbagbe tabi àṣìṣe tabi aimọkan, Arakunrin naa maa sọ pé: Rara Oluwa mi, mi ko ni awijare kankan. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Bẹẹ kọ, dajudaju daadaa kan n bẹ fun ẹ lọdọ wa, ati pe ko si abosi kan fun ẹ lónìí. O sọ pe: Yoo mu kaadi kan jade ti wọn kọ sibẹ pé: Mo n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si ni ododo afi Allahu, mo si n jẹrii pe Muhammad ẹrusin Ọlọhun ni ati Ojiṣẹ Rẹ. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun arakunrin yii pé: Mú òṣùwọ̀n rẹ wa. Arakunrin naa maa sọ ni ẹni ti o n ṣe eemọ pé: Irẹ Oluwa mi! Ki ni òṣùwọ̀n kaadi yii já mọ́ ni ẹ̀gbẹ́ awọn iwe àkọsílẹ̀ yii? Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Abosi ko lee ṣẹlẹ̀ si ẹ lailai. O sọ pe: Wọn yoo gbe awọn iwe àkọsílẹ̀ naa sinu abọ́ òṣùwọ̀n kan, ati kaadi naa sinu abọ́ òṣùwọ̀n kan; bayii ni abọ́ òṣùwọ̀n ti awọn iwe àkọsílẹ̀ wa nibẹ maa di ohun ti o fuyẹ, ti abọ́ òṣùwọ̀n ti kaadi wa ninu rẹ maa tẹṣuwọn ti o maa wuwo, ni Ọlọhun ba maa fi ori jin in.