Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – juwe ẹni ti o ba gbọ oluperun lọ sibi pe ki o maa sọ tẹle e nǹkan ti o ba n wi, nitori naa yio maa sọ iru ọrọ rẹ (oluperun), yatọ si Hayya‘ala mejeeji (Hayya‘alas sọlaah ati Hayya‘alal falaah), yio sọ lẹyin mejeeji pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa yio ṣe asalaatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ti o ba pari irun pipe, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan Ọlọhun a titori rẹ ṣe asalaatu mẹwaa fun un, ati pe itumọ asalaatu Ọlọhun fun ẹru Rẹ ni: Ẹyin Rẹ fun ẹru Rẹ lọdọ awọn malaaika. Lẹyin naa ni o wa paṣẹ pẹlu bibi Ọlọhun leere al-Wasiilah fun oun– ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe oun (al-Wasiilah) naa ni ipo kan ninu al-jannah, ati pe oun lo ga jùlọ ninu rẹ, ko si lẹtọọ bẹẹ ni ko rọrun ayaafi fun ọkan ninu gbogbo awọn ẹru Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ti mo si n tanmọọn ki n jẹ ẹni naa, ati pe o sọ iyẹn – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni ti itẹriba; torí pé dajudaju ti ipo giga yẹn o ba nii wa ayaafi fun ẹnikan, ko wa si ẹni ti o lẹ jẹ ẹnikan yẹn ayaafi oun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -; torí pé oun ni o lọla julọ ninu awọn ẹda. Lẹyin naa o – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe adua al-Wasiilah fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iṣipẹ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – a jẹ tiẹ.