Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro pe kò ní sí awọn apapọ eniyan kan tí wọn joko sí ààyè ijoko kan ti wọn wa dìde láì dárúkọ Ọlọhun nibẹ àyàafi ki wọn dide gẹgẹ bí àwọn ti wọn ko jọ lórí òku kẹtẹkẹtẹ ni ori akitan ati aye oorùn; eleyi ri bẹ nítorípé wọn ṣe airoju kuro nibi ìrántí Ọlọhun, ijoko naa yoo jẹ ìbànújẹ́ fun wọn lọjọ igbende, yoo si jẹ abuku ati àbámọ ti yóò maa wà pẹlu wọn.