Irun pipe ni fifi mọ awọn eeyan wiwọle asiko irun, ati pe awọn gbolohun irun pipe jẹ awọn gbolohun ti wọn ko adisọkan igbagbọ sinu. Ati pe ninu hadīth yii Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye nkan ti wọn ṣe ni ofin nigba ti a ba n gbọ ipe irun, oun naa ni ki ẹni ti n gbọ o maa sọ gẹgẹ bi oluperun ṣe n sọ, nigba ti o ba sọ pe "Allāhu Akbar" ẹni ti o n gbọ naa maa sọ pe: "Allāhu Akbar", bayii ni yio ṣe maa lọ; ayaafi nigba ti oluperun ba sọ pe "ayya‘ala sọlaah", "ayya‘alal falaah", nigba naa ẹni ti n gbọ maa sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh". Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - si tun ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba paara nkan ti oluperun n wi ni ti imọkanga lati inu ọkan rẹ yio wọ alujanna. Itumọ awọn gbolohun irun pipe ni: "Allāhu Akbar": Itumọ rẹ ni pe dajudaju Oun mimọ fun Un ni O tobi julọ, Oun ni o si tun gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ. "Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu ": Itumọ rẹ ni pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu. "Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah": Itumọ rẹ ni pe mo n fi rinlẹ mo si tun n jẹrii pẹlu ahọn mi ati ọkan mi pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ran an ni'ṣẹ, ti itẹle e si jẹ dandan. "Hayya‘ala sọlaah", itumọ rẹ ni pe ẹ wa lọ ki irun, ati pe gbogbo olugbọ yio sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh", itumọ rẹ ni pe ko si ète kankan lati la kuro nibi awọn nkan ti maa n dena titẹle aṣẹ, kò sì tun si agbara lati ṣe e, bẹẹ ni ko si ikapa lori ikankan ninu awọn nkan wọnyii ayaafi pẹlu kongẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga. "Hayya‘alal falaah", itumọ rẹ ni pe ẹ wa sibi okunfa ọla, oun naa ni jijere pẹlu alujanna ati lila kuro nibi ina.