Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣeni lojukokoro lori jijẹ ipe oluperun nigba ti a ba n gbọ ọ, ati pe ìyẹn ni ki a maa sọ nkan ti o n sọ, ni gbolohun gbolohun. Nigba ti o ba wa sọ gbolohun Allāh Akbar àwa naa o wi i lẹyin rẹ, ati pe nigba ti o ba mu gbolohun ijẹrii mejeeji wa, awa naa o mu un wa lẹ́yìn rẹ, Ati pe wọn ṣe ayaafi gbolohun: (Hayya ‘alas sọlāt, Hayya ‘alal falāh) wọn maa sọ lẹyin awọn mejeeji pe: lā haola walā quwwata illā biLlāh.