Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ẹni ti o ba sọ nigba ti o n gbọ oluperun pe Ash-hadu an laa illaha illā Allāhu wahdahu laa sharika laHu" itumọ rẹ ni: Mo n fi rinlẹ wipe dajudaju ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Ọlọhun, ati pe gbogbo nkan ti wọn n sìn yatọ si i ibajẹ ni in. Wa anna muhammadan ‘abduHu wa rosuuluhu" ìtumọ rẹ ni: Dajudaju ẹru ni wọn o ki n jọsin fun un, ati pe ojiṣẹ ni ti ko ki n parọ, Rodiitu bil Laahi Robban" itumọ rẹ ni: Pẹ̀lú ijẹ Oluwa Rẹ, ati ijẹ Ọlọhun Rẹ, ati awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, Wa bi muhammadin rosuula" itumọ rẹ ni: Pẹlu gbogbo nkan ti wọn fi ran an, ti o si mu un de etiigbọ wa, wa bil Islam" itumọ rẹ ni: Pẹlu gbogbo awọn ìdájọ́ Isilaamu bii awọn aṣẹ ati awọn nnkan ti wọn kọ̀, "Diinan” itumọ rẹ ni: Ni ti adisọkan ati itẹle, "Gufiro lahu dhanbuhu" itumọ rẹ ni: Awọn ẹṣẹ kekere.