explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí o ba sọ pe SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa ẹṣẹ rẹ rẹ, wọn si maa fi ori jin in, kódà ki ẹṣẹ rẹ pọ bii ifofo funfun ti o maa n wa lókè agbami odò nigba ti ìgbì rẹ ba n bì ati ti o ba ru sókè

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ẹsan yii maa jẹ ti ẹni tí ó bá wí i ni ojúmọ́ léraléra tabi kélekèle.
  • AT-TESBIIH: Oun ni mimọ Ọlọhun kúrò nibi adinku, AL-HAMDU: Oun ni fifi pípé ròyìn rẹ pẹ̀lú ìfẹ́ ati gbigbetobi.
  • Ohun ti a gbèrò nibi hadiisi naa ni pipa àwọn ẹṣẹ kéékèèké rẹ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ ńlá, dandan ni ki èèyàn tuuba kuro nibẹ.