Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i- wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan kọdi laaarin mi ati laaarin irun mi, ti o kọ ipaya fun mi nibẹ, ti o da kika mi ru ti o si ko iyemeji ba mi nibẹ, Ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sọ fun un pe: Ìyẹn ni Shaitan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ri eyi ti o si fura mọ ọn, dirọ mọ Ọlọhun, ki o si wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, ki o si fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ pẹlu itọ diẹ lẹẹmẹta, Uthman sọ pe: Mo ṣe nnkan ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pa mi láṣẹ pe ki n ṣe, ni Ọlọhun si mu u kuro lọdọ mi.