explain-icon

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe adua laarin iforikanlẹ mejeeji nibi irun rẹ pẹlu awọn adua máàrún yii ti Musulumi ni bukaata ti o tobi si i, ti o si tun ko oore ayé àti ti ọjọ ikẹhin sinu, bii wiwa aforijin ati idaabobo awọn ẹṣẹ ati ṣiṣe amojukuro nibẹ, ati pípé ikẹ, ati lila kuro nibi awọn iruju ati awọn adun ati awọn aisan ati idakọlẹ, ati ibeere imọna lọdọ Ọlọhun sibi ododo pẹlu ifẹsẹmulẹ lori rẹ, ati níní ìgbàgbọ́ àti imọ àti iṣẹ oloore, ati níní dukia halaali ti o mọ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ṣiṣe adua yii lofin nibi ijokoo ti o wa laarin iforikanlẹ mejeeji.
  • Ọla ti n bẹ fun àwọn adua yii latari nkan ti o ko sinu ni oore ayé àti ọjọ ìkẹhìn.