Aishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe: mo sun lẹgbẹ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), mo ṣe afẹku rẹ ni oru (mi o ri), mo wa fi ọwọ mi woo ni ààyè ti o ma ti nkirun ninu yàrá, bayi ni mo kan lojiji pe o nkirun lọwọ ti gigisẹ rẹ mejeeji si wa ni iduro, bẹẹ sì ni o nsọ bayi pe: (mo nwa isọ) mo nṣe atẹgun sọdọ Rẹ (pẹlu ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ) sí mi tabi sí awọn ijọ mi, (ati) pe mo nwa isọra (pẹlu amojukuro Rẹ) ati amojukuro re ti o pọ (kuro nibi ijẹniya Rẹ), (mo wa idaabobo lọdọ Rẹ pẹlu araarẹ) ati pẹlu awọn iroyin rirẹwa Rẹ lọdọ awọn iroyin titobi Rẹ, nigbati o jasipe ẹnikan ò lee ṣọ ni lọdọ Rẹ àyaàfi ìwọ fún rara Rẹ, kò sibi aa salọ fún akoyọ, bẹẹ sì ni kò sibi ti a le sadi lati sa fún Ọlọhun ayaafi ki a sadi Ọlọhun, (Mi o le ṣe onka ẹyin fún irẹ Ọlọhun), mi o nikapa, mi o sì lè dé òpin ati onka lati ka gbogbo idẹra Rẹ tan nitori ikagara mi, bẹẹ ni mi o le ka daada Rẹ tan gẹgẹbi O ṣe lẹtọ si i, koda bi mo ba ṣe igbiyanju ati akitiyan láti ṣe bẹẹ, (gẹgẹ bí Irẹ Ọlọhun ṣe ṣe ẹyìn fún ara Rẹ) Iwọ ni O ṣe ẹyìn fún Pàápàá ara Rẹ, ẹyin ti o ba ọ mu, taani ẹni náà tí o ni ikapa lati mu ẹyin Rẹ wá ní bo ṣe yẹ?!