Ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ti kabara, o maa n dakẹ ni idakẹ díẹ̀ ṣíwájú ki o to ka Fatiha, o maa n bẹ̀rẹ̀ irun rẹ nibẹ pẹlu awọn adura kan, ninu eyi ti o wa ninu awọn adura yii ni ọrọ rẹ pé: "Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi Al-Lahumma Naqqinī Min Khaţāyāya Kamā Yunaqqá Ath-Thawbu 'Illābyađu Mina Ad-Danasi Al-Lahumma Aghsilnī Min Khaţāyāya Bith-Thalji Wa Al-Mā'i Wa Al-Barad", O maa n bẹ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- lati gbe awọn àṣìṣe jìnnà si oun ki oun ma ko si i, ni igbejinna kan ti ipadepọ ko lee ṣẹlẹ pẹlu rẹ, gẹgẹ bi ko ṣe le si ìpàdépọ̀ laaarin ibuyọ oorun ati ibuwọ oorun láéláé, ti oun ba wa ko si i, ki O fọ oun mọ kuro nibẹ ki O mu u kúrò bi wọn ṣe maa n mu ìdọ̀tí kuro lara aṣọ funfun, pe ki O fọ oun mọ kuro nibi awọn àṣìṣe rẹ ki O bu tutu si eyi ti o n jo ti o si gbóná nibẹ, pẹlu awọn nǹkan ti n mọ́ nǹkan ti o tutu yìí; omi ati yinyin.