Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n tọ ìjọ rẹ sọ́nà lọ sibi ìdìrọ̀mọ́ ati ìsádi ti o maa ṣe àǹfààní ti gbogbo nnkan ti a n ṣọ́ra fun ti èèyàn n bẹ̀rù maa lọ pẹ̀lú rẹ nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ si ààyè kan lórí ilẹ̀, boya o wa ni ìrìn-àjò ni, tabi ìjáde ìgbafẹ́, tabi ohun ti o yatọ si ìyẹn: Pẹ̀lú pe ki o dìrọ̀ mọ́ ki o si sádi àwọn gbólóhùn Ọlọhun ti o pe nibi ọla rẹ ati ibukun rẹ ati àǹfààní rẹ, eyi ti o la kuro nibi gbogbo àléébù, níbi aburu gbogbo ẹ̀dá ti o ni aburu lára, ọkàn rẹ maa wa balẹ ni ààyè yẹn nibi gbogbo nnkan ti o ba le ṣe e ni suta lópin ìgbà tí o ba ṣi wa nibẹ.