Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé ipo awọn oluranti Ọlọhun lọpọlọpọ, pe wọn ti dá wà wọ́n si ti ṣáájú àwọn ti wọn yàtọ̀ si wọn pẹlu pe ọwọ wọn tẹ awọn ipo ti o ga julọ ninu alujanna onidẹra, o wa fi wọn we oke Jumdaan ti o da wa laarin awọn oke yókù.