explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé ẹni tí o ba sọ pe: “LAA ILAAHA ILLALLOOH WAHDAHUU LAA SHARIIKA LAHUU, LAHUL MULKU WALAHUL HAMDU, WA UWA ALAA KULLI SHAY’HIN KỌDIIR”, itumọ rẹ ni pe: Ko si ẹni ti a maa jọ́sìn fun ni ododo ayafi Ọlọhun nikan ṣoṣo tí ko ni orogun, Oun nikan si ni O ni ìjọba ti o pe, ti O si ni ẹtọ si ẹyìn pẹ̀lú ìfẹ́ ati gbigbetobi, yatọ si ẹlomiran, Olukapa si ni, nkan kan ko lee ko agara ba A. Ẹni tí ó bá pààrà asikiri nla yii ni ẹẹmẹwaa ni ojúmọ́, o maa gba irú ẹ̀san ti ẹni tí ó bá sọ ẹrú mẹ́rin di olominira ninu àwọn ọmọ Ismail ọmọ Ibrahim, ki ikẹ ati ọla maa ba àwọn méjèèjì- bá gbà, wọ́n dìídì dárúkọ àwọn ọmọ Ismail, ki ọla maa ba a; tori pe àwọn ni wọn jẹ abiyi ju àwọn mìíràn lọ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ọlá ti n bẹ fun asikiri yii, eyi ti o ko ṣíṣe Ọlọhun ni Ọkan pẹ̀lú ìní ẹtọ si ìjọsìn Rẹ, ati ìjọba, ati ẹyin, ati ikapa ti o pe- sínú.
  • Ẹni tí ó maa ri ẹsan asikiri yii ni ẹni tí ó bá sọ ọ léraléra tabi kélekèle.