Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- beere lọwọ awọn saabe rẹ pé: Njẹ ẹ fẹ ki n fun yin ni iro ki n si kọ yin ni eyi ti o daa julọ ninu awọn iṣẹ yin ati eyi ti o niyi julọ ninu rẹ ati eyi ti o ga julọ ninu rẹ ati eyi ti o mọ julọ ninu rẹ lọdọ Ọlọhun Ọba Olukapa- Alagbara ti O gbọnngbọn-? Ti o ga julọ ninu rẹ ninu awọn ipò yin ninu alujanna? Ti o loore julọ fun yin ju ṣíṣe saara pẹlu wura ati fadaka lọ? Ati eyi ti o daa julọ fun yin ju ki ẹ pade ọta yin fun ogun lọ, ki ẹ si ge awọn ọrun wọn ki wọn si ge ọrun yin lọ? Awọn saabe sọ pe: Bẹẹni a fẹ ìyẹn. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Iranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni gbogbo asiko ati lori gbogbo isẹsi.