Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lati ọdọ aburo baba rẹ tii ṣe Abu Toolib ti o si n pọ́kàkà ikú lọ́wọ́- pe ki o pe LAA ILAAHA ILLALLOOH, ki o fi le ṣìpẹ̀ fun un ni Ọjọ́ Àjíǹde, tí o si maa jẹrii fun un pe o gba Isilaamu, ó kọ̀ lati wí gbólóhùn ijẹrii naa ni ìpayà pe ki awọn Quraysh ma bu oun, ti wọn a maa sọ nipa oun pé: O gba Isilaamu tori ibẹru ikú ati ọ̀lẹ! O wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: Ti kii ba ṣe iyẹn ni, mi o ba dùn ọ́ nínú pẹ̀lú ki n wí gbólóhùn ijẹrii naa, mi o ba ṣe nǹkan ti o n fẹ́ titi ti wàá fi yọnu! Ni Ọlọhun ti ọla Rẹ ga wa sọ aaya kalẹ̀ ti n tọka si pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko ni ikapa ìtọ́sọ́nà ti kòńgẹ́ sinu Isilaamu, ṣùgbọ́n Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn nìkan ni O maa n fi ẹni tí Ó ba fẹ ṣe kongẹ. Ati pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n fi ẹ̀dá mọ̀nà pẹlu itọka ati àlàyé ati ìtọ́sọ́nà ati ipepe lọ si ojú ọ̀nà tààrà.