Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọle ti 'Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- ninu ile rẹ, lo ba ri ti wọn ti bo apoti iko nnkan si kekere ti wọn gbe ẹru sinu rẹ pẹlu aṣọ kan ti awọn aworan abẹmi n bẹ nibẹ, awọ oju rẹ si yipada ni ti ibinu nitori Ọlọhun, o si fa a ya, o wa sọ pe: Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun pẹlu awọn aworan wọn. 'Aaisha sọ pe: A si sọ ọ di irọri kan tabi irọri méjì.