Wọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa eyi ti o tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ, ó wa sọ pe: Eyi ti o tobi julọ ninu wọn ni ẹbọ ńlá, oun ni ki o wa akẹgbẹ tabi afijọ fun Ọlọhun nibi ijẹ Ọlọhun Rẹ tabi nibi jijẹ Oluwa Rẹ tabi nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, ati pe ẹṣẹ yìí, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko nii ṣe aforijin rẹ afi pẹlu ironupiwada, ti ẹni ti o ba ṣe e ba ku, o maa ṣe gbere ninu ina. Lẹyin naa, ki ọmọniyan pa ọmọ rẹ ni ti ipaya pe ki o maa jẹun pẹlu rẹ, ati pe pipa ẹmi jẹ eewọ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ rẹ maa tobi ti ẹni ti wọn pa ba jẹ mọlẹbi ẹni ti o pa ènìyàn, ẹṣẹ rẹ maa tobi bakannaa nigba ti o ba ṣe pe erongba ẹni ti o pa eniyan naa ba pa a nitori ipaya ki ẹni ti wọn pa ma baa ba pin ninu arisiki Ọlọhun. Lẹyin naa, ki ọkùnrin ba iyawo ara adugbo rẹ ṣe ṣina, bii ki o gbiyanju lati tan iyawo ara adugbo rẹ titi o fi maa ba a ṣe ṣina ti yoo si gbà fun un, Ati pe ṣina jẹ eewọ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ rẹ maa tobi ti ẹni tí wọ́n bá ṣe ṣina ba jẹ iyawo ara adugbo ti Sharia pàṣẹ ṣíṣe daadaa si i ati wiwu iwa daadaa si i ati biba a lo lọna ti o daa.