Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro apakan awọn iroyin awọn ẹni Alujanna (ọgbà idẹra) ati awọn ẹni ina. Awọn ti wọn pọ̀jù nínú ẹni Alujanna awọn ni: "gbogbo ọlẹ ti kò lágbára rara" itumọ rẹ nipe: ẹni tí o ntẹriba ti o si njirẹbẹ fún Ọlọhun ti o ga jùlọ, ti o rẹ raa rẹ fun Un, debiipe apakan awọn eniyan wọn npe e ni ọlẹ, wọn nyẹpẹrẹ rẹ̀, ẹni ti o yẹpẹrẹ araa rẹ̀ fun Ọlọhun yii, ti o ba fi Allah (Ọlọhun) bura ni enití n rokan si oore Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, Allah yoo sọ di daada, yoo si sọ ohun ti o bura le lori di ootọ, yoo si da lohun ohun ti o beere ati adua rẹ. Awọn ti wọn pọju ninu awọn ẹni iná ni gbogbo "oni iwa to le koko" ohun ni onibinu, ọlọkan líle koko, alajangbila, tabi oni iwa ibajẹ (alaburu) ti kii tẹriba fún daada, "onigirimọkai" ohun ni oni moto moto, Alajẹju (okuonjẹ), ẹni tori gbàngbà, ti nrin irin tanku taloku (irin akọ) oniwa buruku, "oni moto moto" pẹlu aigba ododo wọle, ati ifoju yẹpẹrẹ wo awọn elomiran.