explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan nibi abosi apa kan si apakan ni ọjọ igbedide ni: Nibi awọn ẹjẹ, gẹgẹ bii pipa ènìyàn ati awọn ọgbẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Titobi àlámọ̀rí awọn ẹjẹ, nitori pe ìbẹ̀rẹ̀ maa n jẹ pẹlu eyi ti o ṣe pataki julọ.
  • Awọn ẹṣẹ maa tobi ni ibamu si titobi ibajẹ ti o wa nibẹ, ati ita awọn ẹmi alaiṣẹ silẹ wa ninu eyi ti o tobi julọ ninu ibajẹ, ko si eyi ti o tobi ju u lọ afi ṣíṣe aigbagbọ ati dida orogun pọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.