Awọn saabe wa pẹlu Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni alẹ ọjọ kan, o wa wo òṣùpá- ni ale ọjọ kẹrinla-, o wa sọ pe: Dajudaju awọn olugbagbọ maa ri Oluwa wọn ni ti paapaa pẹlu oju laisi iruju, ati pe wọn ko nii fún papọ mọ́ra wọn, wahala tabi inira ko nii ṣẹlẹ̀ si wọn nibi riri Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga-. Lẹyin naa, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ti ẹ ba ni ikapa lati ge awọn okunfa ti o le yi yin kuro nibi irun asunbaa ati irun Asr, ki ẹ yaa ṣe bẹẹ, ki ẹ si mu mejeeji wa ni pipe ni asiko mejeeji ni janmọọn, dajudaju ìyẹn wa ninu awọn okunfa wiwo oju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka aaya naa: (Wa sabbih bihamdi Robbika qobla tuluu'ish shamsi wa qoblal guruub)