Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ẹnikẹni ninu awọn eeyan ko nii tayọ aaye iṣiro iṣẹ ni ọjọ igbedide lọ si alijanna tabi ina titi ti wọn o fi bi i nipa awọn alamọri kan: Alakọkọọ: Iṣẹmi rẹ nibo ni o pari rẹ sí? Ẹlẹẹkeji: Imọ rẹ njẹ o wa a nitori ti Ọlọhun? Ati pe njẹ o fi ṣiṣẹ ṣe? Ati pe njẹ o mu un de ọdọ ẹni ti o lẹtọọ si i? Ẹlẹẹkẹta: Dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ṣe nibi ẹtọ ni abi níbi eewọ? Ati pe nibo ni o na an si, ṣe ibi nkan ti o yọ Ọlọhun ninu ni abi ibi ti o bi I ninu? Ẹlẹẹkẹrin: Ara rẹ ati agbara rẹ ati alaafia rẹ ati ọdọ rẹ nibo ni o lo o si?