Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lọdọ awọn kan ninu saabe, o wa beere lọwọ wọn lẹẹmẹta lati ṣadehun fun un lori idunnimọ awọn àlámọ̀rí kan: Akọkọ: Ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo pẹlu mimu awọn àṣẹ Rẹ ṣẹ ati jijina si awọn nnkan ẹkọ Rẹ, ati pe wọn ko gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn. Ikeji: Gbigbe awọn irun maraarun-un ti a ṣe wọn ni ọran-anyan duro ni ọsan ati oru. Ikẹta: Gbigbọ ati Itẹle pẹlu daadaa fun ẹni ti o ba n dari alamọri awọn Musulumi. Ikẹrin: Mimaa sọ gbogbo awọn bukaata wọn kalẹ ti Ọlọhun laini beere nnkan kan nibẹ lọwọ awọn eniyan, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa rẹ ohun rẹ nilẹ pẹlu rẹ. Dajudaju awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- ṣiṣẹ pẹlu nnkan ti wọn ṣe adehun le lori, titi ẹni ti o gba hadiisi naa fi sọ pe: Dajudaju mo ri awọn kan ninu awọn saabe wọnyẹn, ti ọrẹ ẹnikan ninu wọn ba jabọ, ko nii sọ fun ẹni kankan ki o ba òun mu u, bi ko ṣe pe o maa sọkalẹ ti o si maa mu u fun ara rẹ.