‘Aaisha ati Ibnu ‘Abbas- ki Ọlọhun yọnu si wọn- n sọ fun wa pé, nigba ti iku de ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o fi egige aṣọ soju rẹ, ti mimi ba ti ṣoro fun un latara awọn irora iku yoo mu u kuro loju rẹ, o wa sọ ninu isẹsi ti o le koko yẹn pé: Ọlọhun ṣẹbi le awọn Juu ati Nasara, O si le wọn jina si ikẹ Rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe wọn kọ mọsalasi lori awọn saare awọn Anabi wọn, bi ko ba ṣe bi alamọri naa ṣe lewu to ni ko nii darukọ rẹ nibi iru aaye yìí, fun idi eyi ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe kọ fun ijọ rẹ kuro nibi ṣíṣe afijọ iṣe yẹn; nitori pe o wa ninu ìṣe awọn Juu ati Nasara, ati pe nitori pe o jẹ oju ọna kan ti o le múni debi ṣiṣe ẹbọ pẹlu Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn.