Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- kọ kuro nibi bibura pẹlu awọn baba, ẹni ti o ba fẹ búra, ko gbọdọ bura afi pẹlu Ọlọhun, ko si gbọdọ bura pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si i. Lẹyin naa, Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe oun ko bura pẹlu rẹ lati igba ti o ti gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti kọ kuro nibi ìyẹn, ni ẹni ti o mọọmọ tabi ni ẹni ti o n gbé ọrọ ẹni ti o yàtọ̀ si i wa ti o bura pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun.