Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe: Ọlọhun fi àkàwé lélẹ̀ fun Isilaamu pẹlu ojú ọ̀nà tààrà ti o tẹ́ ti kò wọ́, tí ògiri méjì n bẹ ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ojú ọ̀nà naa ti wọn rọkirika rẹ, àwọn méjèèjì náà ni àwọn ààlà Ọlọhun, àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣi silẹ n bẹ láàrin ògiri méjì yii, àwọn naa ni àwọn nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ, àwọn aṣọ ẹnu ọ̀nà n bẹ ni àwọn ẹnu ọ̀nà naa ti ko nii jẹ ki ẹni tí n kọjá ri ẹni tí ó wà ninu rẹ, olupepe kan si n bẹ ni ìbẹ̀rẹ̀ ojú ọ̀nà naa ti n dari àwọn èèyàn ti o si n sọ fún wọn pé: Ẹ maa rìn lọ lori ẹ láì fi si etí ati ẹ̀gbẹ́, olupepe yii ni tira Ọlọhun, olupepe mìíràn tun wa ni òkè ọ̀nà naa; olupepe yii, gbogbo igba ti ẹni tí n rìn ni oju ọna naa ba ti fẹ ṣi aṣọ ẹnu ọ̀nà yẹn díẹ̀, o maa jagbe mọ́ ọn, o maa wa sọ fún un pé: Ó ṣe fún ẹ, o ò gbọdọ ṣí i! Ti o ba ṣi i, waa wọ inú ẹ, o ò si nii ni ikapa lati kọ̀ fun ara rẹ lati má wọlé, olupepe yii ni oníwàásù Ọlọhun ninu ọkan gbogbo Musulumi.