Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kilọ kúrò nibi wiwa imọ lati maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, ati lati le fi hàn pé onimimọ bii tiyín ni èmi náà, tabi lati fi ba àwọn omugọ ati awọn ti làákàyè wọn lẹ sọ̀rọ̀ lati ba wọn jiyàn, tabi ki o kọ imọ lati wa ni iwájú ni àpéjọ, ti wọn si maa ti i saaju ẹlòmíràn nibẹ. Ẹni tí ó bá ṣe iyẹn; o ni ẹtọ si iná pẹlu ṣekarimi rẹ ati àìní imọkanga nibi wiwa imọ naa nítorí Ọlọhun.