Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jókòó laarin awọn saabe rẹ, o wa sọ pé: Eyi ni àsìkò ti wọn maa ká imọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, Ziyaad ọmọ Labiid Al-Ansọọriy wá ṣe eemọ- ki Ọlọhun yọnu si i- o wa beere lọwọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa sọ pé: Báwo ni wọ́n ṣe maa ká imọ kúrò lọ́dọ̀ wa?! Ti a si ti ka Kuraani ti a si ha a; mo fi Ọlọhun búra, a o maa ka a, a si maa jẹ ki awọn ìyàwó ati awọn ọmọ wa ka a, ati awọn ọmọ-ọmọ wa, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni ẹni tí n ṣe eemọ pé: O ṣe fun ẹ, irẹ Ziyaad! Tí mo si n ka ọ kun ara àwọn onimimọ nínú àwọn ará ilu Mẹdina! Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé fun un pé: Pipadanu imọ kii ṣe pẹ̀lú pipadanu Kuraani; ṣùgbọ́n pipadanu imọ ni ki èèyàn má lò ó, Taoreeta ati Injiila n bẹ lọdọ awọn Juu ati awọn Kristẹni, tòun ti bẹ́ẹ̀ ko ṣe wọn ni anfaani, wọn ko si ṣe àǹfààní latara erongba àwọn méjèèjì; òun naa ni ki wọn lo ohun ti wọn mọ̀.