explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n funni niroo pe dajudaju ninu awọn ami opin aye ni sisunmọra igba, Ti ọdún si maa rekọja gẹgẹ bi oṣu ṣe n rekọja, Ati pe oṣu maa rekọja gẹgẹ bi ọsẹ ṣe n rekọja, Ati pe jimọ (ọsẹ) maa rekọja gẹgẹ bi ọjọ kan ṣe n rekọja, Ati pe ọjọ maa rekọja gẹgẹ bi wakati kan ṣe n rekọja, Ati pe wakati maa rekọja ni iyara ti o lagbara gẹgẹ bi wọn ṣe maa n jo ewé igi dabinu.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ninu awọn àmì igbẹyin aye ni yiyọ alubarika kuro ninu igba ati yiyara rẹ (igba).