Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe oun ko fi àdánwò kan kan silẹ lẹ́yìn oun ti o ni àwọn ọkùnrin lára ju àwọn obìnrin lọ, ti o ba jẹ ọkan ninu awọn araale rẹ ni, o le ṣẹlẹ̀ lati ọdọ rẹ nibi iyapa sharia lati tẹle e, ti o ba si jẹ àjòjì si i, o le ṣẹlẹ̀ pẹlu iropọ mọ́ ọn ati dida wà pẹ̀lú rẹ, ati aburu ti o le ti ibẹ jáde.