Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ṣe alaye pe Ọlọhun Ọba sọ wipe Oun ti ṣe àbòsí ni eewọ fun ara Oun, O si ṣe àbòsí ni eewọ láàrin àwọn ẹ̀dá Rẹ̀; nitori naa ki ẹni kankan má ṣe abosi fun ẹlòmíràn, Ati pe gbogbo ẹda ni o ṣina kúrò ni oju ọna otitọ afi pẹlu itọsọna ati kòńgẹ́ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba beere rẹ lọwọ Ọlọhun, Ọlọhun yoo fun un ni kongẹ ati itọsọna, Ati pe awọn ẹda n bukaata si Ọlọhun, wọn si nilo Rẹ ni gbogbo awọn bukaata wọn, ẹnikẹni ti o ba beere lọwọ Ọlọhun, yoo gbọ́ bukaata rẹ, yoo si tó o, Wọ́n sì ń dẹ́ṣẹ̀ lóru àti ní ọ̀sán, Ọlọhun Ọ̀gá Ògo a sì máa bo àṣírí, a si maa ṣe amojukuro nígbà tí ẹrú bá tọrọ àforíjìn, Wọn ko si ni ikapa lati fi ara ni Ọlọhun tabi ṣe E ni anfaani kankan, Ti wọn ba si wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o paya Ọlọhun ju lọ, ipaya wọn ko ṣe alekun ọlá Ọlọhun, Ti wọn ba si wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o yapa Ọlọhun jù, iyapa wọn ko din nǹkan kan kù ninu ọla Ọlọhun; torí pé ọ̀lẹ ni wọn ti wọn si n bukaata si Ọlọhun ni gbogbo iṣesi ati asiko ati aaye, Oun si ni Ọlọ́rọ̀, mimọ ni fun Un, Ti wọn ba duro ni ààyè kan, èèyàn wọn ati alujannu wọn, akọkọ wọn ati ìkẹyìn wọn, ti wọn wa n tọrọ nǹkan lọ́dọ̀ Ọlọhun, ki O wa maa fun ẹni kọọkan wọn ni ohun ti n beere, ìyẹn ko din nǹkan kan ku ninu ohun ti n bẹ ni ọdọ Ọlọhun, o da bii abẹrẹ ti wọn ba ki i bọ inu òkun, lẹyin naa ki wọn wa mu u jáde, nǹkan kan ko dínkù ninu òkun pẹ̀lú ìyẹn, eléyìí ri bẹ́ẹ̀ tori pípé ọrọ̀ Rẹ, ògo ni fun Un. Ati pe Ọlọhun, mimọ ni fun Un, pa iṣẹ́ awọn ẹru Rẹ mọ, O si ṣe àkọsílẹ̀ wọn, lẹyin naa yoo san wọn ni ẹsan lori rẹ ni Ọjọ Ajinde, ẹni tí ó bá ri ẹsan iṣẹ rẹ ni oore, ki o dúpẹ́ fun Ọlọhun lori pe O fi ṣe kongẹ lati tẹle àṣẹ Rẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rí ẹ̀san iṣẹ́ rẹ̀ ní ohun mìíràn yàtọ̀ sí èyí, kò gbọ́dọ̀ dá ẹnì kan lẹ́bi bí kò ṣe ẹ̀mí rẹ̀ ti maa n pàṣẹ aburu, èyí tí ó mú kí ó pàdánù.