explain-icon

Àlàyé

Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Ojisẹ Ọlọhun, dajudaju ẹnikan ninu wa n ri alamọri kan ninu ẹ̀mí rẹ ti o wa sínú ẹ̀mí, ṣùgbọ́n o tobi láti sọ ọ jáde, débi pe o nífẹ̀ẹ́ ki oun jẹ eeru ju ki o sọ ọ jade lọ, Bayii ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe Ọlọhun tobi ni ẹẹmeji, o si dupẹ fun Ọlọhun pe O da ete èṣù pada si royiroyi lasan.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Alaye pe èṣù maa n retí ìkángun olugbagbọ pẹlu royiroyi; ki o le da wọn pada lati inu igbagbọ lọ si inu aigbagbọ.
  • Alaye lilẹ èṣù pẹlu awọn oni igbagbọ nigba ti ko lee ni ikapa afi lori royiroyi.
  • O tọ́ fun olugbagbọ ki o ṣẹri kuro nibi awọn royiroyi èṣù, ki o si ti i dànù.
  • Ṣíṣe lofin gbigbe Ọlọhun tobi nibi nnkan ti a fẹ tabi eemọ latari nnkan tabi nnkan ti o jọ ọ ninu awọn alamọri.
  • Ṣíṣe lofin ṣíṣe ibeere Musulumi lọdọ onimimọ nipa gbogbo nnkan ti o ba ru u loju.