Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, sọ fun wa pe ina aye yii jẹ ọkan ninu aadọrin awọn ẹya ina Jahannama, Gbígbóná iná ọjọ́ ìkẹyìn lágbára ju gbígbóná iná ayé lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀ ṣe déédéé gbígbóná ina ayé. Wọ́n sọ pé: Ìwọ Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, iná ayé yìí ti tó láti fi fi ìyà jẹ àwọn ti wọn ba wọ̀ ọ́, O sọ pé: Ina Jahannama ju ina ayé lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀ da gẹgẹ bii rẹ nibi gbígbóná gidi gan.