Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣekilọ kuro nibi awọn iran eniyan meji kan ninu awọn ara ina, ko ri wọn, wọn ko si si ni igba aye rẹ, sugbọn wọn maa wa lẹyin rẹ: Iran akọkọ: Awọn ijọ kan ti awọn ọrẹ ti wọn da gẹgẹ bi awọn iru maalu ti wọn gun n bẹ lọwọ wọn, wọn maa n fi i na awọn eniyan, awọn ni awọn ọlọpaa ati awọn ti wọn n kun àwọn alabosi lọ́wọ́, àwọn ti wọn maa n na awọn eniyan lọna ailẹtọọ. Ati pe iran ikeji ni: Awọn obinrin kan ti wọn ti bọ aṣọ iparamọ ati itiju eyi ti wọn sábà maa n ṣẹda obinrin lori rẹ. Iroyin wọn ni: Wọn maa wọ aṣọ lódodo, wọn maa wa ni ihoho ni ìtumọ̀; nitori pe wọn wọ aṣọ ti o fẹlẹ ti o n ṣe iroyin ara, wọn si bo apakan ninu ara wọn, ti wọn ṣi apakan rẹ kalẹ; ni ti afihan ẹwà, Ti wọn maa n yi awọn ọkan awọn ọkunrin sọ́dọ̀ wọn pẹlu aṣọ wọn ati ìrìn akọ wọn, ti wọn maa n yẹ awọn ejika wọn, ti wọn maa n yi awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn lọ sibi iyẹgẹrẹ ati iyipada ti awọn ko si, Ninu awọn iroyin wọn ni pé: Awọn ori wọn da gẹgẹ bii ike ẹyin rakunmi ti o tẹ, wọ́n maa n jẹ ki orí wọn tobi pẹ̀lú wiwe aṣọ mọ́rí ati ohun ti o jọ ọ. Ati pe afiwe pẹlu ike ẹyin ràkúnmí rí bẹ́ẹ̀ fun lilọ soke irun wọn ati awọn irun-dídì wọn sórí wọn, ati lílọ́ rẹ pẹlu nnkan ti wọn fi dì í titi o fi maa tẹ̀ si ẹgbẹ kan ni ori gẹgẹ bii ike maalu ṣe maa n tẹ si ẹgbẹ kan. Ẹni ti o ba wa pẹlu awọn iroyin yii, a jẹ pe adehun iya ti o le koko yii n bẹ lara wọn pẹlu pe ki wọn ma wọ alujanna ki wọn si ma gbọ́ oorun rẹ ki wọn si ma sunmọ ọn, ati pe oorun alujanna wọn maa n gbọ́ ọ lati ọna ti o jinna.