explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – fún wa niroo pé Alujanna ati Ina súnmọ́ ènìyàn gẹgẹ bi okùn bàtà tó máa n wà lókè ẹsẹ̀ ṣe súnmọ́, nitori pé ó ṣee ṣe kí eniyan ṣe iṣẹ ijọsin kan, kí iṣẹ yii sì mu un rí iyọnu Ọlọhun, yoo sì mu un wọ Alujanna, ó sì ṣee ṣe kó dá ẹṣẹ kan, kí ẹ̀ṣẹ̀ yii sì jẹ́ okunfa fun un tí yoo fi wọ Ina.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ìmúni nífẹ̀ẹ́ láti maa ṣe rere kódà bí ó bá kéré, ati ilenisa kuro nibi ṣiṣe aburu kódà bí ó bá kéré.
  • kò sí tabi-ṣugbọn fún musulumi nibi pé kí ó kó irankan ati ìbẹ̀rù papọ ninu aye rẹ̀, kí ó sì maa bẹ Ọlọhun Ọba ni gbogbo igba pé kí Ó mú oun duro sinsin lori ododo títí oun ó fi là, tí iṣesi tí oun wà ò fi nii kó itanjẹ bá oun.