Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pé dajudaju awọn nkan tí ẹ̀mí eniyan n fẹ́ ni o wa ní ayika Iná ọ̀run, gẹgẹ bii ṣiṣe awọn nkan tí Ọlọhun ṣe ní eewọ tabi ikudiẹ-kaato nibi awọn ọranyan; Nitori naa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ifẹẹnu rẹ̀ nibi ìyẹn, onitọhun ti lẹtọọ sí wiwọ Ina ọ̀run, àti pé dajudaju àwọn nkan tí ẹmi eniyan koriira rẹ̀ ni o wa ní ayika Alujanna; gẹgẹ bii ṣíṣe àwọn nkan tí Ọlọhun pa wá láṣẹ rẹ̀ déédé ati gbigbe àwọn nkan eewọ jù sílẹ̀ àti ṣíṣe sùúrù lori wọn, tí eniyan bá wá tiraka, tí ó sì gbiyanju pẹ̀lú ẹmi ara rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, onitọhun ti lẹtọọ sí wiwọ Alujanna.