explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pé ẹnikẹni tí ó bá kú, tí kò mu orogun kankan pẹlu Ọlọhun, Alujanna ni ibupadasi rẹ̀ kódà bí wọ́n bá jẹ ẹ niya nitori apakan ninu awọn ẹṣẹ rẹ̀, ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ku, ni ẹniti n mu orogun pẹlu Ọlọhun, onitọhun yoo wọ inu Ina gbere.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ọla tí ń bẹ fun ìṣọlọ́hun-lọ́kan, ati pé ó jẹ́ òkùnfà fún ìgbàlà kúrò nibi wíwọ inu Ina gbere.
  • Isunmọ Alujanna ati Ina sí ọmọniyan, ati pé kò sí nkankan laarin ọmọniyan ati awọn mejeeji bikoṣe iku.
  • Iwani ní iṣọra kuro nibi ẹbọ, kekere rẹ̀ ati pupọ rẹ̀; nítorí pe jijina si ẹbọ ni ọna igbala kuro nibi wíwọ Ina.
  • Ariwoye inu awọn iṣẹ ni igbẹyin rẹ̀.