explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọrọ nipa awọn nkan meji tó ṣe pé tí Musulumi bá dúnní mọ́ wọn, dajudaju yóò wọ Alujanna. Ikinni: Ṣíṣọ́ ẹnu kuro nibi sísọ nkan tí ó maa fa ibinu Ọlọhun Ọba, Èkejì: Ṣíṣọ́ abẹ́ kuro nibi ìṣekúṣe; nítorí pé awọn oríkèé ara meji wọnyi, ẹ̀ṣẹ̀ máa n waye latara wọn lọpọlọpọ ìgbà.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ṣíṣọ́ ẹnu ati abẹ́ jẹ́ ọ̀nà lati wọ inu Alujanna.
  • Wọ́n dá ẹnu ati abẹ́ ṣà lẹ́ṣà; nitori pe awọn mejeeji ni orisun aluba ati adanwo tí ó tobi julọ fún eniyan ni aye ati ọrun.