explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe eyi ti o tobi ju ninu awọn okùnfà ti yoo mu èèyàn wọ alujanna méjì ni, àwọn naa ni: Ipaya Ọlọhun ati iwa dáadáa. Ìpayà Ọlọhun: Oun ni ki o fi aabo si aarin rẹ ati iya Ọlọhun, pẹ̀lú ṣíṣe àwọn nǹkan ti O pàṣẹ lati ṣe, ati jíjìnnà si awọn nǹkan ti O kọ̀. Iwa dáadáa: O maa jẹ pẹlu títú ojú ká, ati ṣíṣe dáadáa, ati ki èèyàn ma jẹ ki suta kan ẹlòmíràn. Eyi ti o tobi ju ninu awọn okùnfà ti yoo mu awọn èèyàn wọ ina meji ni, àwọn naa ni: Ahọn ati Abẹ́. Lara àwọn ẹṣẹ ahọ́n ni: Irọ́, ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn, òfófó, ati awọn mìíràn. Lara àwọn ẹṣẹ abẹ́ ni: Ṣìná, ati ibalopọ láàrin ọkùnrin si ọkùnrin, ati awọn mìíràn.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Wiwọ alujanna ni àwọn okùnfà ti o nii ṣe pẹ̀lú Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ninu wọn ni: Ibẹru Rẹ, ati awọn okunfa ti o nii ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn, ninu wọn ni: Ìwà dáadáa.
  • Ewu ahọn fun ẹni tí ó ni ín, ati pe o wa ninu awọn okùnfà wíwọ iná.
  • Ewu ìfẹ́-adùn ati awọn ìwà ibajẹ fun ọmọniyan, ati pe wọn wa ninu awọn okùnfà ti o pọ julọ lati wọ iná .