Ọkùnrin kan wa sọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: Ràkúnmí mi ti parun, ba mi wa ràkúnmí kan ti maa gun ti o maa gbe mi de ibi ti mo n lọ, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mu àwáwí wa fun un pe oun ko nii nǹkan ti o le gun, arákùnrin kan ti o wa nibẹ wa sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, maa júwe ẹni tí ó máa fun un ni nǹkan ọ̀gùn fun un, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé alabaakẹgbẹ nibi ẹsan ni fun ẹni ti o ba fun un ni nnkan ọ̀gùn; tori pe oun ni o júwe rẹ fun ẹni tí ó ni bukaata si i.